Ghana pegede lati kopa ninu abala to ku nidije AFCON

0
44

Orile-ede Ghana ti je orile-ede akoko ti yoo pegede ni abala asepari ti idije AFCON fun iko awon egbe agbaboolu ti ojo-ori won ko ju odun metadinlogun lo to n lo lowo ni Gabon.

Ghana fagbahan Gabon ti won n gbalejo idije naa pelu ami ayo marun un si odo ni papa isere Stade de Port Gentil.

Eric Ayiah ati Emmanuel Toku, Patmos Arhin ni won ti fakoyo seyin lati je ki Ghana pegede bayii. Lojo Aiku to koja ni won fagbahan Cameroun pelu ami ayo merin si odo.

Bibori ninu idije yii ti fun Ghana loore ofe lati kopa ninu idije agbaye ti oje wewe ti ko tii pe omo odun metadinlogun to m bo lona. Awon Panthers ti ja bayii nitori pe orile-ede Guinea naa fagbahan won pelu ami ayo marun un si ookan ninu idije ti won fi side eto ohun. Die lara awon to fakoyo ninu idije naa ni Fahd Moubeti, Danladi Ibrahim, Ayiah- Toku ati Arhin.

Ni abala to gbeyin ninu egbe A, orile-ede Ghana yoo koju Guinea ni papa isere Stade de l’Amitie in Libreville lojo Abameta to m bo. Nigbati Gabon ati Cameroun yoo jo maa koo pa lasiko kan naa ni Port Gentil.