Ẹ ran Naijiria lọwọ lati gbogun ti airisẹ

Ademola Adepoju

0
282
Ẹ ran Naijiria lọwọ lati gbogun ti airisẹ

Orile ede Niajiria ti beere fun iralowo lati odo orile ede Amerika lati gbogun ti airisẹ to n ba won wọya ija bi asọ lorile ede yii.

Akowe agba fun ajo to n ri si  eto isẹ ati igbanisisẹ lorile ede Naijiria (Federal Ministry of Labour and Employment), William Alo, lo n beere iranlowo yii “ Lati gbogun ti airise to n koju orile ede Naijiria.”

Lasiko to n gba asoju eka ile-ise to n mojuto eto ise lati orile ede Amerika , ni eyi ti  Kurt Petermeyer, oludari eka to n mojuto oludari eto aabo ati ilera eka, dari won ,so pe awon wa si orile ede ede Niajiria lati mo ona ti awon yoo gba lati ran won lowo nipa gbigbogun ti airise lorile ede yii .

Ogbeni ilo tesiwjau pe, pipese ile-ise ironilagbara ati ohun ikose yoo din iwa adigunjale ati ogun airise ku laarin awon ọdọ.

Gege bi ohun ti o wa ninu atejade kan lati ile –ise to n mojuto eto ise ati igbanisisẹ so  pe wiwa ti awon asoju orile ede Amerika wa si orile ede Naijiria ni lati tun tesiwaju lori ipinnu won lati pese eto ironilagbara ati lati wa ona miiran ti won yoo tun fi ran orile ede Naijiria lowo lati gbogun ti airisẹ .

Ademola Adepoju